Hymn 442 Oluwa, mo mba O pade nihin Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oluwa, mo mba O pade nihin,
Igbagbo mu mi wo ohun orun;
Ngo fi agbara ro mo ore Re,
Ngo si fi ara are mi ti O.
2 Emi ‘o je akara Olorun
Emi o mu wain orun pelu Re;
Nihin, ngo so eru aiye kale,
Nihin, ngo gba idariji ese
3 Emi ko ni ‘ranwo mi lehin Re,
Apa Re l’o to lati fara ti;
O to wayi, Oluwa mi, o to,
Agbara mi mbe ninu ipa Re.
4 Temi ni ese, Tire l’ododo,
Temi l’ebi, Tire l’eje ‘wenu;
Ewu, abo, aon alafia mi
L’ Eje at’ ododo Re, Oluwa.
5 Gbat’ a ba dide t’ a si palemo,
T’a ko akara ati wain kuro;
Sibe Iwo wa nihin, Oluwa,
Lati je Orun ati Asa mi.
6 Bi ase yi tin de ti o sin lo,
O nran wa leti ase nla torun;
O nfi ayo didun ase nah an,
Ase ayo yawo Od- Agutan. Amin.