Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 435 Odo Agutan Olorun Lyrics

Hymn 435 Odo Agutan Olorun Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Odo Agutan Olorun,
Jo we mi ninu eje Re;
Sa je kin mo ‘fe Re, ‘gbana
Irora dun, iku l’ ere.

2 Fa okan mi kuro l’aiye,
K’ o je k’ o se Tire titi;
Fi edidi Re s’ aiya mi,
Edid’ ife titi aiye.

3 A! awon wonni ti yo to,
T’ o f’ iha Re se ‘sadi won!
Nwon fi O se agbara won,
Nwon nje, nwon si nmu ninu Re.

4 O kun wa loju p’ Olorun
Fe m’awa yi lo sin’ ogo!
Pe, O so eru d’ om’ Oba,
Lati ma je faji lailai!

5 Baba, mu wa ronu jinle,
K’ a le mo ise nlanla Re;
Ma sai tu okun ahon wa,
K’ a le so ibu ife Re.

6 Jesu, Iwo l’ olori wa,
‘Wo l’ a o teri wa ba fun,
‘Wo l’ a o fi okan wa fun,
B’ a ku, b’ a wa, k’ a je Tire. Amin.

Exit mobile version