Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 431 Jesu ayo okan gbogbo Lyrics

Hymn 431 Jesu ayo okan gbogbo Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Jesu ayo okan gbogbo,
Orisun ‘ye, imole wa,
Nin’ opo bukun aiye yi,
Lainitelorun: a to wa.

2 Otiti Re duro lailai,
‘Won gb’ awon to kepe O la;
Awon ti o wa O, ri O,
Bi gbogbo nin’ ohun gbogbo.

3 A to O wo, Onje Iye,
A fe je l’ara Re titi;
A mu ninu Re, Orisun,
Lati pa ongbe okan wa.

4 Ongbe Re sa ngbe okan wa,
Nibikibi t’ o wu k’ a wa;
‘Gbat’ a ba ri O awa yo.
A yo nigbat’ a gba O gbo.

5 Jesu, wa ba wa gbe titi,
Se akoko wa ni rere;
Le okunkun ese kuro,
Tan ‘mole Re mimo s’aiye. Amin.

Exit mobile version