Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 430 Mo nlo; talaka Mi mbe lodo nyin Lyrics

Hymn 430 Mo nlo; talaka Mi mbe lodo nyin Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 “Mo nlo; talaka Mi mbe lodo nyin,
E le ma sore fun won b’e ti nfe.”

2 Eyi ni ogun t’ Olugbala wa
Fi sile f’ awon Tire, k’o to lo:

3 Wura on jufu ko, otosi ni,
K’a ma ran won lowo nitori Re.

4 Eru nla ko, ogun t’o l’oro ni
Ti nf’ ilopo ’bukun f’ eni ntore.

5 T’iwa k’ ise na bi? L’ojude wa
Ko ni talaka at’ asagbe wa?

6 Ohun irora awon t’ iya nje,
Ko ha nke si wa lati f’ anu han?

7 Okan t’o gb’ogbe, okan ti nsise;
Ekun opo, at’ alaini baba!

8 On t’o f’ ara Re fun wa, si ti fi
Etu orun f’ awa iranse Re.

9 Ko s’otosi kan ti ko le sajo,
F’eni tosi ju lo; agbara ni.

10 Isin mimo ailabawon l’eyi,
Ti Baba mbere lowo gbogbo wa. Amin.

Exit mobile version