Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 429 Wo orison ohun rere Lyrics

Hymn 429 Wo orison ohun rere Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 ‘Wo orison ohun rere
Awa fe se ‘fe re;
Ohun wo l’ a le fi fun O,
Oba gbogbo aiye?

2 L’ aiye yi, ‘Wo ni otosi,
T’ o je enia Re:
Oruko won n’ Iwo njewo
Niwaju Baba Re.

3 ‘Gba nwon ba nke n’ inira won,
Ohun Re l’ awa ngbo;
‘Gba ba si nse itoju won,
Awa nse ‘toju Re.

4 Jesu, ma sai gba ore wa,
Si f’ ibukun Re si;
Ma f’ ibukun Re s’ ebun wa,
Fun awon t’ a nfi fun.

5 Fun Baba, Omo at’ Emi,
Olorun ti a nsin;
Ni ki a ma fi ogo fun,
Titi aiyeraiye. Amin.

Exit mobile version