Hymn 42 Oluwa ’kore. ’Wo l’a nyin Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oluwa ’kore. ’Wo l’a nyin;
Ileri Re ’gbani ko ye;
Orisi igba si nyipo,
Ododun kun fun ore Re;
Lojo oni, awa dupe;
Je k’ iyin gba okan wa kan.
2 B’ akoko ’rugbin mu way o;
B’ igba erun nmu oru wa;
’Gbat’ owo ojo ba nrinle;
Tabi’ igbat’ ikore bap on,
’Wo Oba wa l’a o ma yin;
’Wo l’ alakoso gbogbo won.
3 Ju gbogbo re lo, nigbati
Owo Re fun opo ka ’le;
Gbat’ ohun ayo gbilekan,
B’ eda ti nko ire won jo;
Awa pelu y’o ma yin O
Ore Re ni gbogbo wan pin.
4 Oluwa ’Kore, Tire ni
Ojo ti nro, orun tin ran:
Irugbin ti a gbin sile,
Tire l’ ogbon tin mu dagba:
Otun lebun Re l’ ododun;
Otun n’iyin Re l’ enu wa. Amin.
