Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 419 Oba awon eni mimo Lyrics

Hymn 419 Oba awon eni mimo Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Oba awon eni mimo,
T’o mo ’ye awon ’rawo;
Opo enit’ eda gbagbe
Wa yika ite Re lai;

2 ’Mole ti kuku aiye bo,
Ntan ’mole roro loke,
Nwon je om’- alade lorun,
Eda gbagbe won laiye.

3 Lala at’ iya won fun O,
Eda ko rohin re mo;
Iwa rere won farasin,
Oluwa nikan l’o mo.

4 Nwon farasin fun wa, sugbon
A ko won s’ iwe iye:
Igbagbo, adura, suru,
Lala on ’jakadi won.

5 Nwon mo isura Re lohun;
Ka wa mo won, Oluwa,
Nigbat’ O ba nsiro oso,
Ti mbe lara ade Re. Amin.

Exit mobile version