Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 417 Wa k’a da m’ awon ore wa Lyrics

Hymn 417 Wa k’a da m’ awon ore wa Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Wa k’a da m’ awon ore wa,
Ti nwon ti jere na;
N’ ife k’a f’ okan ba won lo
Sode orun lohun.

2 K’awon t’aiye d’orin won mo,
T’ awon t’o lo s’ogo;
Awa l’aiye, awon l’orun,
Okan ni gbogbo wa.

3 Idile kan n’nu Krsit ni wa.
Ajo kan l’a si je;
Isan omi kan l’ o ya wa,
Isan omi iku.

4 Egbe ogun kan t’ Olorun,
Ase Re l’ a sin se;
Apakan ti wodo na ja,
Apakan nwo lowo!

5 Emi wa fere dapo na,
Y’o gb’ Ade bi ti won;
Ao yo s’ami Balogun wa,
Lati gbo ipe Re.

6 Jesu, so wa, s’amona wa,
Gbat’ oniko ba de;
Oluwa, pin omi meji,
Mu wa gunle l’ayo. Amin.

Exit mobile version