Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 416 F’ awon enia Re t’ o lo ’simi Lyrics

Hymn 416 F’ awon enia Re t’ o lo ’simi Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 F’ awon enia Re t’ o lo ’simi,
Awon ti o f’ igbagbo jewo Re,
K’a yin oruko Re, Olugbala,
Alleluya!

2 Iwo l’ apata won at’ odi won,
Iwo ni Balogun won l’oju ’ja,
Iwo ni imole okunkun won.
Alleluya!

3 Je ki awon omo- ogun Re l’aiye,
Jagun nitoto b’awon ti ’gbani;
Kin won le gba ade ogo bi won,
Alleluya!

4 Idapo ibukun wo l’o to ’yi!
Awa nja nihin, awon nyo lohun!
Be Tire kanna l’awa at’ awon.
Alleluya!

5 Gbat’ ija ba ngbona, ti ogun nle,
A dabi eni ngb’ orin ayo won;
Igboiya a si de, at’ agbara.
Alleluya!

6 Ojo nlo, orun wa fere wo na,
Awon ajagun toto y’o simi.
Didun ni isimi Paradise,
Alleluya!

7 Lehin eyi ojo ayo kan mbo,
Awon mimo yo dide n’nu ogo;
Oba ogo yio wa larin won.
Alleluya!

8 Lat’ opin ile, lat’ opin okun,
Ogunlogo nro wo ’bode pearli;
Nwon nyin Baba, Omo, ati Emi.
Alleluya! Amin.

Exit mobile version