Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 415 Tal’ awon wonyi b’ irawo Lyrics

Hymn 415 Tal’ awon wonyi b’ irawo Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Tal’ awon wonyi b’ irawo,
Niwaju ite mimo,
Ti nwon si de ade wura,
Egbe ogo wo l’eyi?
Gbo! nwon nko Alleluya,
Orin iyin Oba won!

2 Tali awon ti nko mana,
T’ a wo l’ aso ododo?
Awon ti aso funfun won
Y’o ma funfun titi lai,
Beni ki y’o gbo lailai:
Nibo l’ egbe yi ti wa?

3 Awon wonyi l’ o ti jagun,
F’ ola Olugbala won;
Nwon jijakadi tit’ iku,
Nwon ki b’ elese kegbe:
Wonyi ni ko sa f’ ogun,
Nwon segun nipa Kristi.

4 Wonyi l’ okan won ti gbogbe,
Ninu danwo kikoro;
Wonyi li o ti f’ adura,
Mu Olorun gbo tiwon;
Nisisiyi nwon segun,
Olorun re won l’ekun.

5 Awon wonyi l’ o ti sora,
Ti nwon fi ife won fun Kristi;
Nwon si y’ ara won si mimo,
Lati sin nigbagbogbo;
Nisisiyi li orun,
Nwon wa l’ ayo l’ odo Re. Amin.

Exit mobile version