Hymn 411 Wa sodo mi, alare Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 “Wa sodo mi, alare,
Ngo fun nyin n’ isimi,”
A! ohun didun Jesu,
Ti o p’ elese wa.
O nso ti ore- ofe,
Ati t’ alafia,
Ti ayo ti ko lopin,
T’ ife ti ko le tan.
2 “E wa, enyin omo Mi,
Ngo fun nyin n’ imole”
A! ohun ife Jesu,
Ti nle okunkun lo;
Awa kun fun banuje,
A ti s’ ona wa nu;
Imole y’o m’ ayo wa,
Oro y’o m’ orin wa.
3 “E wa, enyin ti ndaku,
Ngo fun nyin ni iye:”
Ohun alafia Jesu,
T’ o f’ opin s’ ija wa.
Oju ota wa koro,
Ija si le pupo;
Sugbon ’Wo fun wa n’ipa,
A bori ota wa.
4 “Enikeni t’ o ba wa,
Emi ki o ta nu;”
A! ohun suru Jesu,
T’ o le ’yemeji lo!
Ninu ife iyanu,
T’o p’ awa elese,
B’a tile je alaiye,
S’odo Re, Oluwa. Amin.
