Hymn 41 Yin Olorun Oba wa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Yin Olorun Oba wa;
Egbe ohun iyin ga;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
2 Yin Enit’o da orun
Ti o nran lojojumo;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
3 Ati osupa loru
Ti o ntanmole jeje;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
4 Yin Enit’ o nm’ojo ro
T’ o nmu irugbin dagba;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
5 Enit’ o pase fun ’le
Lati mu eso po si;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
6 Yin fun ikore oko,
O mu ki aka wa kun;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
7 Yin f’onje t’ o ju yi lo,
Eri ’bukun ailopin;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
8 Ogo f’ Oba olore:
Ki gbogbo eda gberin:
Ogo fun Baba, Omo,
At’ Emi: Metalokan. Amin.