Hymn 397 Olorun ogbon at’ ore Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Olorun ogbon at’ ore,
Tan ’mole at’ oto,
Lati f’ ona toro han wa,
Lati to ’sise wa.
2 Lati to ’pa wa n’nu ewu,
Li arin apata;
Lati ma rin lo larin won,
K’a m’ oko wa gunle.
3 B’ o’r ofe Re tin mu wa ye,
K’ a ko won b’ eko Re,
A wa lati to omo wa
Ni gbogbo ona Re.
4 Li akoko, pa ife won,
On ’gberaga won run;
K’a fi ona mimo han won,
Si Olugbala won.
5 A fe woke nigbakugba,
K’ a to apere Re;
K’a ru ’beru, on ’reti won,
K’a tun ero won se.
6 A fe ro won lati gbagbo,
Ki nwon f’ itara han;
Ki a mase lo ikanra,
’Gbat’ a ba le lo’ fe.
7 Eyi l’a f’ igbagbo bere,
Ogbon t’o t’oke wa;
K’a f’ eru omo s’ aiya won,
Pelu ife mimo.
8 K’a so ’fe won ti nte s’ibi,
Kuro l’ ona ewu;
K’a fi pele te okan won,
K’a fa won t’ Olorun. Amin.
