Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 388 Yo awon ti nsegbe, sajo eni nku Lyrics

Hymn 388 Yo awon ti nsegbe, sajo eni nku Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Yo awon ti nsegbe, sajo eni nku,
F’anu ja won kuro ninu ese,
Ke f’awon ti nsina, gb’ eni subu ro,
So fun won pe, Jesu le gba won la.
Yo awon ti nsegbe, sajo eni nku,
Alanu ni Jesu, yio gbala.

2 Bi nwon o tile gan, sibe O nduro
Lati gb’ omo t’o ronupiwada;
Sa f’ itara ro won, si ro won jeje.
On o dariji, bi nwon je gbagbo.
Yo awon ti nsegbe, &c.;

3 Yo awon ti nsegbe, – ise tire ni;
Oluwa yio f’agbara fun O;
Fi suru ro won pada s’ona toro;
So f’ asako p’ Olugbala ti ku.
Yo awon ti nsegbe, sajo eni nku,
Alanu ni Jesu, yio gbala. Amin.

Exit mobile version