Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 381 Ninu oru ibanuje Lyrics

Hymn 381 Ninu oru ibanuje Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ninu oru ibanuje
L’ awon egbe ero nrin;
Nwon nkorin ’reti at’ ayo,
Nwon nlo sile ileri.

2 Niwaju wa nin’ okunkun,
Ni imole didan ntan;
Awon arakonrin nsate,
Nwon nrin lo li aifoya.

3 Okan ni imole orun,
Ti ntan s’ ara enia Re;
Ti nle gbogbo eru jina,
Ti ntan yi ona wa ka.

4 Okan ni iro ajo wa,
Okan ni igbagbo wa;
Okan l’ eni t’ a gbekele,
Okan ni ireti wa.

5 Okan l’ orin t’ egberun nko,
Bi lati okan kan wa;
Okan n’ ija, okan l’ ewu,
Okan ni irin orun.

6 Okan ni inu didun wa,
L’ ebute ainipekun;
Nibiti Baba wa orun,
Y’o ma joba titi lai.

7 Nje k’ a ma nso, arakonrin,
T’ awa ti agbelebu:
E je k’ a ru, k’ a si jiya,
Tit’ a o fi ri ’simi.

8 Ajinde nla fere de na,
Boji fere si sile;
Gbogbo okun y’o si tuka,
Gbogbo lala y’ o si tan. Amin.

Exit mobile version