Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 379 Omo Olorun nlo s’ ogun Lyrics

Hymn 379 Omo Olorun nlo s’ ogun Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Omo Olorun nlo s’ ogun,
Lati gb’ ade Oba:
Opagun Re si nfe lele,
Tal’ o s’ omogun Re?

2 Enit o le mu ago na,
T’ o le bori ’rora,
T’ o le gbe agbelebu Re,
On ni Omogun Re.

3 Martir ikini t’ o ko ku,
T’ o r’ orun si sile;
T’o ri Oluwa re loke,
T’ o pe, k’o gba on la.

4 T’ on ti ’dariji l’enu,
Ninu ’rora iku,
O bebe f’ awon t’ o npa lo:
Tani le se bi re?

5 Egbe mimo; awon wonni
T’Emi Mimo ba le;
Awon akoni mejila,
Ti ko ka iku si:

6 Nwon f’aiya ran ida ota,
Nwon ba eranko ja;
Nwon f’orun won lele fun ku,
Tani le se bi won?

7 Egbe ogun, t’ agba, t’ ewe,
T’okunrin t’obinrin;
Nwon y’ite Olugbala ka,
Nwon wo aso funfun.

8 Nwon de oke orun giga,
N’nu ’se at’ iponju:
Olorun fun wa l’ agbara
K’ a le se bi won. Amin.

Exit mobile version