Hymn 378 Omogun Krist, dide Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Omogun Krist, dide,
Mu hamora nyin wo:
Mu ’pa t’ Olorun fi fun nyin,
Nipa ti Omo Re.
2 Gbe ’pa Olorun wo,
T’ Oluwa omogun;
Enit’ o gbekele Jesu,
O ju asegun lo.
3 Ninu ipa re nla,
On ni ki e duro;
’Tori k’ e ba le jija na,
E di hamora nyin.
4 Lo lat’ ipa de ’pa,
Ma ja, ma gbadura;
Te agbara okunkun ba,
E ja k’ e si segun.
5 Lehin ohun gbogbo,
Lehin gbogbo ija,
K’ e le segun n’ipa Kristi,
K’ e si duro sinsin. Amin.