Hymn 373 Didan l’ opagun wa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Didan l’ opagun wa, o ntoka s’ orun,
O nfonahan ogun, s’ ile won orun!
Lar’naginju l’a nrin, l’ ayo l’ a ngbadura,
Pel’ okan isokan l’ a ’m’ on’ orun pon.
Didan l’ opagun wa, O ntoka s’ orun,
O nfonahan ogun, s’ ile won orun.
2 Jesu Oluwa wa, l’ ese Re owo,
Pelu okan ayo l’ omo Re pade:
A ti fi O sile, a si ti sako.
To wa Olugbala si ona toro.
Didan l’ opagun wa, &c.;
3 To wa l’ ojo gbogbo, l’ ona t’ awa nto,
Mu wan so s’ isegun l’ or iota wa;
K’ Angel Re s’ asa wa gb’ oju orun su;
Dariji, si gba wa lakoko iku.
Didan l’ opagun wa, &c.;
4 K’ a le pelu awon Angeli loke,
Lati jumo ma yin n’ite ife Re:
’Gbat’ ajo wa ba pin, isimi y’o de,
At’ alafia, at’ orin ailopin.
Didan l’ opagun wa, &c.; Amin.