Hymn 37 Didun n’ise na, Oba mi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Didun n’ise na, Oba mi,
Lati ma yin oruko Re,
Lati se ’fe Re l’ owuro,
Lati so oro Re l’ ale
2 Didun l’ ojo ’simi mimo,
Lala ko si fun mi loni:
Okan mi, ma korin iyin
Bi harpu Dafidi didun.
3 Okan mi o yo n’ Oluwa,
Y’o yin ise at’ oro Re
Ise ore Re tip o to !
Ijinle si ni imo Re.
4 Emi o yan ipo ola
’Gb’ ore- ofe ba we mi nu
Ti ayo pupo sib a mi,
Ayo mimo lat’ oke wa.
5 ’Gbana, ngo ri, ngo gbo, ngo mo
Ohun gbogbo ti mo ti nfe;
gbogbo ipa mi y’o dalu
Lati se ’fe Re titi lai. Amin.