Hymn 369 Ese d’ eru? wo, Jesu ni Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ese d’ eru? wo, Jesu ni!
On tikare l’ o ntoko;
E ta ’gbokun si afefe,
Ti y’o gbe wa la ibu,
Lo si ilu
’Bit’ olofo ye sokun.
2 B’a ko mo ’bit’ a nlo gun si,
Ju b’a ti ngbohin re lo;
Sugb’a ko ’hun gbogbo sile,
A tele ihin t’a gbo;
Pelu Jesu,
A nla arin ibu lo.
3 A ko beru igbi okun;
A ko si ka iji si;
Larin ’rukerudo, a mo
P’ Oluwa mbe nitosi;
Okun gba gbo,
Iji sa niwaju Re.
4 B’ ayo wa o ti to lohun,
Iji ki ja de ibe:
Nibe l’ awon ti nsota wa
Ko le yow a lenu mo:
Wahala pin
L’ ebute alafia na. Amin.
