Hymn 368 Amona okan at’ Oga Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Amona okan at’ Oga
Awon ero l’ona orun,
Jo ba wa gbe, ani awa
T’a gbekele Iwo nikan;
Iwo nikan l’a f’okan so,
B’a ti nrin l’ona aiye yi.
2 Alejo at’ ero l’a je,
A mo p’aiye ki se ’le wa:
Wawa l’a nrin ’le osi yi,
L’aisimi l’a nwa oju Re;
A nyara s’ ilu wa orun,
Ile wa titilai l’oke.
3 Iwo ti o rue se wa,
T’ o si fi gbogbo re ji wa;
Nipa Re l’a nlo si Sion,
T’a nduna ile wa orun;
Afin Oba wa ologo,
O nsunmo wa, b’a ti nkorin.
4 Nipa imisi ife Re,
A mu ona ajo wa pon;
S’ idapo Ijo- akobi,
A nrin lo si oke orun,
T’awa t’ayo ni ori wa:
Lati pade Balogun wa. Amin.