Hymn 367 E ma te siwaju, Kristian ologun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 E ma te siwaju, Kristian ologun,
Ma tejumo Jesu t’o mbe niwaju;
Kristi Oluwa wa ni Balogun wa,
Wo! asia Re wa niwaju ogun,
E ma te siwaju, Kristian ologun,
Sa tejumo Jesu t’o mbe niwaju.
2 Ni oruko Jesu, ogun Esu sa,
Nje Kristian ologun, ma nso si ’segun;
Orun apadi mi ni hiho iyin.
Ara, gbohun nyin ga, gb’ orin nyin soke
E ma te siwaju, &c.;
3 Bi egbe ogun nla, n’ Ijo Olorun,
Ara, a nrin l’ona t’awon mimo rin;
A ko yaw a n’ipa, egbe kan ni wa,
Okan n’ireti, l’eko, okan n’ife.
E ma te siwaju, &c.;
4 Ite at’ ijoba, wonyi le parun,
Sugbon Ijo Jesu y’o wa titi lai;
Orun apadi ko le bor’ Ijo yi,
A n’ileri Kristi, eyi ko le ye.
E ma te siwaju, &c.;
5 E ma ba ni kalo, enyin enia,
D’ohun nyin po mo wa, l’orin isegun;
Ogo, iyin, ola, fun Kristi Oba,
Eyi ni y’o ma je orin wa titi.
E ma te siwaju Kristian ologun,
Sa tejumo Jesu t’o mbe niwaju. Amin.