Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 36 Ayo l’ ojo ’simi fun mi Lyrics

Hymn 36 Ayo l’ ojo ’simi fun mi Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ayo l’ ojo ’simi fun mi,
At’ agogo at’ iwasu:
Gbat’ a ba mi n’nu ’banuje
Awon l’o nmu inu mi dun.

2 Ayo si ni wakati na
Ti mo lo n’nu agbala Re;
Lati mo adun adura
Lati gba manna oro Re.

3 Ayo ni idahun “Amin”
T’o gba gbogbo ile na kan,
Lekokan l’o ndun t’ o nrole,
O nkoja lo sodo Baba.

4 B’ aiye fe f’ agbara de mi
Mo ise ijo mefa re;
Oluwa, jo, tu ide na,
K’ o so okan mi d’ominira. Amin.

Exit mobile version