Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 356 Jesu npe wa, losan, lorun Lyrics

Hymn 356 Jesu npe wa, losan, lorun Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Jesu npe wa, losan, lorun,
Larin irumi aiye;
Lojojumo l’ a ngbohun Re
Wipe, “Kristian, tele Mi.”

2 Awon Apostili ‘gbani,
Ni odo Galili ni:
Nwon ko ile, ona, sile,
Gbogbo nwon si nto lehin.

3 Jesu npe wa, kuro ninu
Ohun aiye asan yi;
Larin afe aiye, O nwi
Pe, “Kristian e feran Mi.”

4 Larin ayo at’ ekun wa,
Larin lala on’ rorun;
Tantan l’ o npe l’ ohun rara
Pe, “Kristiani e feran Mi.”

5 Olugbala nip’ anu Re,
Je ki a gbo ipe Re;
F’ eti ‘gboran fun gbogbo wa,
K’ a fe O ju aiye lo. Amin.

Exit mobile version