Hymn 35 Akoko odun at’ osu Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Akoko odun at’ osu,
Gbogbo won l’ Olorun da;
Ojumo ni fun ise wa,
Oru si ni lati sun.
2 O si da ojo isimi;
N’nu ’jo meje, O mu ’kan,
K’ enia ba le r’ aye se
Ati sin Olorun wa.
3 L’ ojo mefa ni k’ a sise,
B’ o ti ye ni ki a se;
L’ ojo keje je k’ a pejo,
Ni ile Olorun wa.
4 L’ ojo na yi a ngbadura,
A nkorin didun si I
A sin yin Olorun l’ ogo,
T’ o ju ohun gbogbo lo.
5 Nisisiyi korin iyin,
T’ Olorun Oluwa wa:
Korin didun, korin soke,
Ni yiyin Oluwa wa. Amin.