Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 340 Jesu Oluwa, Oba mi Lyrics

Hymn 340 Jesu Oluwa, Oba mi Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Jesu Oluwa, Oba mi,
Gbohun mi nigbati mo npe,
Gbohun mi lati ’bugbe Re,
Rojo ore- ofe sile;
Oluwa mi, mo feran Re,
Je ki nle ma feran Re si.

2 Jesu, mo ti jafara ju,
Ngo se le fe O b’o ti ye?
Em’ o se le gb’ ogo Re ga,
Ati ewa oruko Re.
Oluwa mi. &c.;

3 Jesu, kil’ o ri ninu mi,
Ti ’fe na fi po to bayi?
Ore Re si mi tip o to!
O ta gbogbo ero mi yo!
Oluwa mi, &c.;

4 Jesu, ’Wo o je, orin mi,
Tire l’ aiya at’ okan mi:
Tire ni gbogbo ini mi,
Olugbala, ’Wo ni temi:
Oluwa mi, mo feran Re,
Je ki nle ma feran Re si. Amin.

Exit mobile version