Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 337 Awa ko orin ife Re Lyrics

Hymn 337 Awa ko orin ife Re Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Awa ko orin ife Re,
Obangiji Oba Ogo;
Ko s’ ohun ti lalasi Re,
Ola Re ko si nipekun.

2 N’nu ife l’o s’ eda aiye,
O da enia sinu re;
Lati ma s’ akoso gbogbo;
E korin ’fe Eleda wa.

3 Lojojumo l’ O ntoju wa,
O si mbo, O si nsike wa;
Beni ko gba nkan lowo wa,
Korin ’yin s’ onibu ore.

4 O ri wa ninu okunkun,
Pe, a ko mo ojubo re;
N’ ife O fi ona han wa;
E korin ife Olore!

5 N’ ife O fi Jesu fun wa,
Omobibi Re kansoso;
O war a wa lowo ese;
A yin ’fe Re Olugbala!

6 Ife Re ran oro Re wa,
Ife Re l’ o si wa leti,
Ife Re si mu wa duro;
E korin ore- ofe Re.

7 Gbogbo eda kun fun ’fe Re,
Oluwa wa, Oba aiye;
Gbogbo agbaiye, e gberin,
Orin ife Olorun wa. Amin.

Exit mobile version