Hymn 336 ’Gbat aiye yi ba koja Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 ’Gbat aiye yi ba koja,
Ti orun re ba si wo,
Ti a ba wo ’nu ogo,
T’ a bojuwo ehin wa;
’Gbana, Oluwa, ngo mo
Bi gbese mi tip o to.
2 ’Gba mo ba de ’b’ ite Re,
L’ ewa ti ki se t’emi;
’Gba mo ri O b’ o ti ri,
Ti mo fe O l’ afetan;
’Gbana Oluwa, ngo mo
Bi gbese mi ti po to.
3 ’Gba mba ngbo orin orun,
Ti ndun bi ohun ara,
Bi iro omi pupo:
T’ o si ndun b’ ohun duru;
’Gbana Oluwa, ngo mo
Bi gbese mi ti po to.
4 Oluwa, jo, je k’a ri
Ojiji Re l’ aiye yi;
K’ a mo adun dariji,
Pelu iranwo Emi;
Kin tile mo l’ aiye yi,
Die ninu gbese mi.
5 Ore- ofe l’ o yan mi,
L’ o yo mi ninu ewu;
Jesu l’ Olugbala mi,
Emi so mi di mimo,
Ko mi ki nfi han l’aiye,
Bi gbese mi ti po to.! Amin.