Hymn 334 Oruko kan mbe ti mo fe Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oruko kan mbe ti mo fe
Mo fe ma korin re;
Iro didun ni l’ eti mi,
Oruko didun ni.
2 O so ife Olugbala,
T’ o ku lati ra mi;
O so t’ eje Re ’yebiye,
Etutu f’ elese.
3 O so ti iyonu Baba,
Ti o ni s’ Omo Re;
O m’ ara mi ya, lati la
Aginju aiye ja.
4 Jesu, Oruko ti mo fe,
T’ o si dun l’ eti mi;
Ko s’ eni mimo kan l’aiye,
T’ o mo b’ o tip o to.
5 Oruko yi j’ orun didun,
L’ ona egun t’ a nrin;
Yio tun ona yangi se,
T’o lo s’od’ Olorun.
6 Nibe pelu awon mimo,
Ti nwon bo nin’ ese,
Emi o korin titun ni,
T’ ife Jesu si mi. Amin.