Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 332 Olugbala mi, ife Re Lyrics

Hymn 332 Olugbala mi, ife Re Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Olugbala mi, ife Re
Ha tobi be si mi?
Wo, mo f’ ife mi, okan mi,
At’ aiya mi fun O.

2 Mo fe O nitori ’toye,
Ti mo ri ninu Re;
Mo fe O nitori iya,
T’ o f’ ara da fun mi.

3 Bi Iwo ti je Olorun,
T’ a f’ ogo de l’ ade;
Iwo ko ko awo enia,
T’ o kun fun iyonu.

4 ’Wo je k’ a bi O l’ enia,
Sugbon ’Wo ko l’ ese;
K’ awa le ri b’ Iwo ti ri,
K’ a le se b’ O ti se.

5 K’ a dabi Re ninu ife,
L’ ewa iwa mimo;
B’ a ti nwoju Re, k’ a ma lo,
L’ at’ ogo de ogo. Amin.

Exit mobile version