Hymn 330 Jesu, kiki ironu Re Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Jesu, kiki ironu Re,
Fi ayo kun okan;
Sugbon k’a ri O l’o dun ju,
K’a simi lodo Re.
2 Enu ko so, eti ko gbo,
Ko ti okan wa ri;
Oko t’o sowon, t’o dun bi
Ti Jesu Oluwa.
3 Ireti okan ti nkanu,
Olore elese;
O seun f’ awon ti nwa O,
Awon t’o ri O yo.
4 Ayo won, enu ko le so,
Eda ko le rohin;
Ife Jesu, b’o tip o to,
Awon Tire l’o mo.
5 Jesu, ’Wo ma je ayo wa,
’Wo sa ni ere wa;
Ma je ogo wa nisiyi,
Ati titi lailai. Amin.