Hymn 325 Om’ Olorun a ko ri O Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Om’ Olorun a ko ri O,
’Gba t’ o wa s’ aiye iku yi;
Awa ko ri ibugbe Re,
Ni Nasareti ti a gan;
Sugbon a gbagbo p’ ese Re
Ti te ita re kakiri.
2 A ko ri O lori igi,
T’ enia buburu kan O mo:
A ko gbo igbe Re, wipe,
“Dariji won, tor’ aimo won.”
Sibe, a gbagbo pe, ’ku Re
Mi aiye, o si m’ orun su.
3 A ko duro leti boji,
Nibiti a gbe te O si;
A ko joko ’nu yara ni,
A ko ri O loju ona.
Sugbon a gbagbo p’ angeli
Wipe, “Iwo ti ji dide.”
4 A ko r’ awon wonni t’ o yan,
Lati ri ’goke- rorun Re;
Nwon ko fi iyanu woke,
Nwon si f’ eru dojubole.
Sugbon a gbagbo pen won ri O.
Bi O ti ngoke lo s’ orun.
5 Iwo njoba l’ oke loni,
’Wo si mbukun awon Tire;
Imole ogo Re ko tan
Si aginju aiye wa yi.
Sugbon, a gba oro Re gbo,
Jesu, Olurapada wa. Amin.