Hymn 323 Nihin l’ ayida wa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Nihin l’ ayida wa;
Ojo, erun, nkoja,
Ile ni nyan, ti o si nsa,
’Tanna dada si nku:
Sugbon oro Jesu duro,
“Ngo wa pelu re,” ni On wi.
2 Nihin l’ ayida wa;
L’ ona ajo orun;
N’nu gbagbo, ’reti, at’ eru,
N’nu ’fe s’ Olorun wa:
A nsaika oro yi si po!
“Ngo wa pelu re,” ni On wi.
3 Nihin l’ ayida wa;
Sugbon l’ arin eyi,
L’ arin ayidayid’ aiye,
Okan wa ti ki yi;
Oro Jehofa ki pada;
“Ngo wa pelu re,” ni On wi.
4 Ona alafia:
Immanueli wa;
Majemu ti ore- ofe,
Lai nwon ki yipada;
“Nki yipada,” l’ oro Baba,
“Mo wa pelu re,” ni On wi. Amin.