Hymn 306 Oluwa Olorun mi, se ’fe Re Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Oluwa Olorun mi, se ’fe Re:
Nki o mi ’ra,
Nko ni dide, ki nma ba sesi ta.
Owo na nu,
Ti nmu mi ro mo aiya Baba mi
Ni isimi.
2 Okan ti njijakadi, ni Kristi
Nfun l’ agbara;
Iwaiya ija Re oru, ’gbati
Ko s’ enikan,
Ju Baba at’ Angeli rere kan
Ti ntu ninu.
3 “Baba, ’fe mi ko, Tire ni k’a se”
Be l’ Omo wi.
K’ eyi je ’siri wa larin gbogbo
Lala aiye,
K’a le ro mo aiya Re titi lai
Ni isimi. Amin