Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 305 Jesu l’ Olusagutan mi Lyrics

Hymn 305 Jesu l’ Olusagutan mi Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Jesu l’ Olusagutan mi,
Ore eniti ki ye!
Ko s’ ewu bi mo je Tire,
T’ On si je temi titi.

2 Nib’ odo omi iye nsan,
Nibe l’o nm’ okan mi lo;
Nibiti oko tutu nhu,
L’o nf’ onje orun bo mi.

3 Mo ti fi were sako lo,
N’ ife O si wa miri;
L’ ejika Re l’o gbe mi si,
O f’ ayo mu mi wa ‘le.

4 Nko beru ojiji iku,
B’ Iwo ba wa lodo mi;
Ogo Re ati opa Re,
Awon l’o ntu mi ninu.

5 Iwo te tabili fun mi;
‘Wo d’ ororo sori mi;
A! ayo, na ha ti po to!
Ti nt’ odo Re wa ba mi.

6 Be, lojo aiye mi gbogbo,
Ore re ki o ye lai:
Olusagutan, ngo yin O,
Ninu ile Re titi. Amin.

Exit mobile version