Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 295 Baba orun, nin’ oro Re Lyrics

Hymn 295 Baba orun, nin’ oro Re Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Baba orun, nin’ oro Re
Ni ogo orun ntan;
Titi lai l’ a o ma yin O
Fun Bibeli mimo.

2 Opo ’tunu wa ninu re,
Fun okan alare;
Gbogbo okan ti ongbe ngbe,
Nri omi iye mu.

3 Ninu re l’ Alafia wa,
Ti Jesu fi fun wa;
Iye ainipekun si wa
N’nu re fun wa gbogbo.

4 Iba le ma je ayo mi,
Lati ma ka titi,
Kim ma ri ogbon titun ko,
N’nu re lojojumo.

5 Oluwa Oluko orun,
Mase jina si mi;
Ko mi lati fe oro Re,
Ki nri Jesu nibe. Amin.

Exit mobile version