Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 288 Mo f’ iyin ailopin Lyrics

Hymn 288 Mo f’ iyin ailopin Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Mo f’ iyin ailopin
Fun Olorun Baba,
Fun ore aiye mi,
At’ ireti t’ orun.
O ran Omo Re ayanfe,
Lati ku fun ese aiye.

2 Mo f’ iyin ailopin
Fun Olorun Omo;
T’ O f’ eje Re we wa,
Kuro ninu egbe:
Nisisiyi O wa l’ Oba,
O nri eso irora Re.

3 Mo f’ iyin ailopin
Fun Olorun Emi:
Eni f’ agbara Re,
So elese d’ aye.
O pari ise igbala,
O si fi ayo kun okan.

4 Mo f’ ola ailopin
Fun Olodumare,
’Wo Ologo meta,
Sugbon okansoso;
B’ O ti ju imo wa lo ni,
A o ma f’ igbagbo yin O. Amin.

Exit mobile version