Hymn 279 Emi ’bukun ti a nsin Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Emi ’bukun ti a nsin
Pelu Baba at’ Oro,
Olorun aiyeraiye;
Emi Mimo, gbo ti wa.
2 Emi Mimo, ’Daba orun,
Iri tin se lat’ oke,
Emi ’ye at’ ina ’fe;
Emi Mimo, gbo ti wa.
3 Isun ipa at’ imo,
Ogbon at’ iwa- mimo,
Oye, imoran, eru;
Emi Mimo, gbo ti wa.
4 Isun ife, Alafia,
Suru, ibisi ’gbagbo,
’Reti, ayo ti ki tan;
Emi Mimo, gbo ti wa.
5 Emi Afonahan ni,
Emi tin mu ’mole wa,
Emi agbara gbogbo;
Emi Mimo, gbo ti wa.
6 ’Wo t’ o mu Wundia bi,
Eni t’ orun t’ aiye mbo,
T’a ran lati tun wa bi;
Emi Mimo, gbo ti wa.
7 ’Wo ti Jesu t’ oke ran
Wa tu enia Re ninu,
Kin won ma ba nikan wa;
Emi Mimo, gbo ti wa.
8 ’Wo t’O nf’ ore kun Ijo,
T’O nfi ife Baba han,
T’O nmu k’o ma ri Jesu;
Emi Mimo, gbo ti wa.
9 Iwo ti nf’ onje iye,
At’ otito na bo wa,
Ani, On t’O ku fun wa;
Emi Mimo, gbo ti wa.
10 F’ ebun meje Re fun ni,
Ogbon, lati m’ Olorun,
Ipa lati ko ota;
Emi Mimo, gbo ti wa.
11 Pa ese run lokan wa,
To ife wa si ona,
B’a ban se O, mu suru;
Emi Mimo, gbo ti wa.
12 Gbe wa dide, b’a subu,
Ati nigba idanwo,
Sa pe wa pada pele;
Emi Mimo, gbo ti wa.
13 Wa, k’O mu ailera le,
F’ igboya fun alare,
Ko wa l’ oror t’a o so;
Emi Mimo, gbo ti wa.
14 Wa ran okan wa lowo,
Lati mo otito Re,
Ki ’fe wa le ma gbona;
Emi Mimo, gbo ti wa.
15 Pa wa mo l’ona toro
Baw a wi nigb’a nsako,
Ba wa bebe l’ adura,
Emi Mimo, gbo ti wa.
16 Eni Mimo, Olufe,
Wa gbe inu okan wa;
Ma fi wa sile titi:
Emi Mimo, gbo ti wa. Amin.
