Hymn 263 Kukuru l’oj’ aiye wa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
APA I
1 Kukuru l’oj’ aiye wa,
Die l’ojo aro;
Aiye ti ko l’opin mbe,
Nibit’ ekun ko si.
2 A! ere wo l’o to yi:
Isimi ailopin;
At’ ile nla t’o dara,
F’elese bi awa.
3 L’aiye yi awa njagun,
L’orun a o d’ade,
Ade ti ki dibaje,
Ti y’o ma dan titi.
4 Nibe l’awa o gbe ri
Enit’ a gbekele:
Iye awon to ba mo,
Ni yio je tire.
5 Owuro ojo n ambo,
Okunkun y’o ka lo,
Awon olokan pipe
Y’o ma ran bi orun.
6 Olorun at’ ipin wa,
N’nu ekun ore Re,
Nibe ni a o ma wo
A o yin lojukoju.
APA II
1 A! ilu daradara,
Mo fe lati ri o,
Opolopo ni nsunkun
Fun ’fe lati ri O.
Ogo ti mbe ninu re,
Ororo ni f’okan,
Egbogi ni fun aisan,
Ife ni, iye ni.
2 Ibugbe kansoso na,
Paradise ayo,
Nibit’ omije ki de,
Erin ni ’gbagbogbo;
Odagutan ti a pa,
On ni ewa ibe;
Awon ti a rapada
Nkorin ibukun Re.
3 Okuta jasper didan,
L’a fi mo odi re;
Oniruru okuta
L’a fi te ita re;
Ilu na dara pupo,
O mo bi kristali;
Awon mimo ni ngbe ’be,
Kristi n’ Ipile re.
4 Okun ti ko n’ebute,
Ojo ti ko n’opin;
Orisun ’tura didun,
Fun awon alare.
L’or’ Apat’ aiyeraiye
L’a mo odi re si;
Tire l’ade asegun,
Tire l’ade wura. Amin.
