Hymn 261 A nsoro ile ’bukun ni Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 A nsoro ile ’bukun ni
Ile didan at’ ile ewa;
’Gbagbogbo l’a nso t’ogo re;
Y’o ti dun to lati de ’be!
2 A nsoro ita wura re,
Oso odi re ti ko l’egbe;
’Faji re ko se f’enu so;
Y’o ti dun to lati de ’be!
3 A nso p’ ese ko si nibe,
Ko s’aniyan at’ ibanuje,
Pelu ’danwo lode, ninu;
Y’o ti dun to lati de ’be!
4 A nsoro orin iyin re,
Ti a ko le f’orin aiye we;
B’o ti wu k’orin wa dun to:
Y’o ti dun to lati de ’be!
5 A nsoro isin ife re,
Ti agbada t’ awon mimo nwo,
Ijo akobi ti oke;
Y’o ti dun to alti de ’be!
6 Jo, Oluwa, t’ibi t’ire,
Sa se emi wa ye fun orun;
Laipe, awa na yio mo,
B’o ti dun to lati de ’be. Amin.