Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 259 Lai lodo Oluwa Lyrics

Hymn 259 Lai lodo Oluwa Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 “Lai lodo Oluwa!”
Amin, beni k’o ri.
Iye wa ninu oro na,
Aiku ni titi lai.
Nihin ninu ara,
Mo sako jina si;
Sibe, alale ni mo nfi,
Ojo kan sunmole!

2 Ile Baba loke,
Ile okan mi ni;
Emi nfi oju igbagbo
Wo bode wura re!
Okan mi nfa pipo,
S’ile na ti mo fe,
Ile didan t’ awon mimo,
Jerusalem t’ Orun.

3 Awosanma dide,
Gbogbo ero mi pin;
Bi adaba Noa, mo nfo
Larin iji lile.
Sugbon sanma kuro,
Iji si rekoja,
Ayo ati Alafia
Si gba okan mi kan.

4 Loro ati l’ale,
Losan ati loru,
Mo ngbo orin orun, bori
Rudurudu aiye.
Oro ajinde ni,
Hiho isegun ni,
Lekan si, “Lai lod’ Oluwa”
Amin, beni k’o ri. Amin.

Exit mobile version