Hymn 258 Lehin aiye okunkun yi Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Lehin aiye okunkun yi,
Ogo ailopin mbe;
At’ ilu ayo ti ki tan,
T’ oju eda ko ri.
2 Ilu ewa! oju wa ’ba
Ri ’daji ayo re,
Okan wa iba ti fe to
Lati f’ aiye sile!
3 Aisan on ’rora ki de ’be,
Ibanuje ko si;
Ilera ni lojo gbogbo,
Adun ti ko lopin.
4 Oru ko si n’ ilu wonni,
Osan ni titi lai;
Ese, orison egbe wa,
Ko le wo ’be titi.
5 A! k’ ireti orun wa yi
Mu okan wa gbona,
K’ igbagbo at’ ife nla yi
M’ ero wa lo soke.
6 Oluwa, ’lanu se wa ye
Fun agbala orun;
Si so f’ okan wa k’o dide
Dapo m’ awon t’ orun. Amin.
