Hymn 256 Ile ayo kan wa Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ile ayo kan wa
Ti o jina,
Ni b’ awon mimo wa:
Nwon nran b’ orun;
A! nwon nkorin didun,
Yiye, l’ Olugbala wa:
Ki iyin Re k’ o ro,
Yin yin lailai.
2 Wa sile ayo yi,
Wa, wa k’ a lo;
E se nsiyemeji?
E se nduro?
Ao wa l’alafia,
Kuro l’ ese at’ aro:
A o ba o joba,
L’ayo lailai.
3 Oju gbogbo won ndan,
N’ ile ayo;
N’ ipamo Baba wa,
Ife ki ’ku;
Nje sure lo s’ ogo,
Gba ade at’ ijoba;
T’ o mo ju orun lo,
Joba titi. Amin.