Hymn 252 Olor’ Alufa giga kan Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Olor’ Alufa giga kan,
To gb’eda wa wo farahan,
Nibiti tempil’ orun wa,
Ile Olorun t’a ko ko.
2 On, bi Onigbowo enia,
To t’eje ’yebiye s’ile,
To npari ’se nla Re l’orun,
Olugbala, Ore enia.
3 B’ o tile goke lo s’orun,
O nfoju ife wo aiye,
Enit’ o nje oko enia,
O mo ailera eda wa.
4 Alabajiya wa si mo
Bi ’rora wa si tip o to;
L’orun, o si nranti sibe,
Omije on ’waiya ja Re.
5 Ninu ibanuje okan,
Eni ’Banuje pin n’nu re;
O mba wa daro edun wa,
O sin ran ojiya lowo.
6 K’ a k’edun wa lo sodo Re,
Pelu ’gboiya, nibi ite;
K’a toro agbara orun,
Lati yow a nigba ibi. Amin.
