Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 250 Ile ’bukun kan wa Lyrics

Hymn 250 Ile ’bukun kan wa Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ile ’bukun kan wa
Lehin aiye wa yi,
Wahala, irora,
At’ekun ki de be;
Igbagbo y’o dopin,
Ao de reti l’ade,
Imole ailopin
Ni gbogbo ibe je.

2 Ile kan sit un mbe,
Ile Alafia,
Awon Angel rere
Nkorin n’nu re lailai;
Y’ite ogo Re ka
L’awon egbe mimo
Nwole, nwon nteriba
F’ Eni Metalokan.

3 Ayo won tip o to!
Awon to ri Jesu
Nibit’ o gbe gunwa,
T’a si nfi ogo fun;
Nwon nkorin iyin Re
Ati t’isegun Re,
Nwon ko dekun rohin
Ohun nla t’o ti se.

4 W’oke, enyin mimo,
E le iberu lo
Ona hiha kanna
L’ Olugbala ti gba;
E fi suru duro
Fun igba die sa,
T’erin- t’erin l’On o
Fi gba nyin sodo Re. Amin.

Exit mobile version