Hymn 25 Ojo ‘simi at’ ayo Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ojo ‘simi at’ ayo,
Ojo inu didun,
Ogun fun ibanuje
Ojo dida julo;
Ti awon eni giga
Niwaju ite Re
Nko mimo, mimo, mimo,
S’eni Metalokan.
2 L’ ojo yi ni ‘mole la,
Nigba dida aiye:
Ati fun igbala wa
Krisit jinde loni:
L’ ojo oni l’ Oluwa,
Ran emi t’ orn wa;
Ojo ologo julo
T’ o ni ‘mole pipe.
3 Orisun ‘tura ni O,
Laiye aginju yi:
L’ ori Re, bi ni Pisga
L’ a nwo ‘le ileri.
Ojo ironu didun
Ojo ife mimo,
Ojo ajinde, lati
Aiye, si nkan orun.
4 L’ oni s’ ilu t’ are mu
Ni Manna t’ orun bo;
Si ipejopo mimo
N’ ipe fadaka ndun.
Nibiti Ihin – rere
Ntan imole mimo,
Omi iye nsan jeje
Ti ntu okan lara.
5 K’ a r’ ore- ofe titun
L’ ojo ‘simi wa yi,
K’ a side ‘simi t’ o ku
F’ awon alabukun.
Nibe k’ a gbohun soke
Si Baba at’ Omo
Ati si Emi Mimo,
N’ iyin Metalokan. Amin.