Hymn 249 Ile ewa wonni, b’ o ti dara to Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ile ewa wonni, b’ o ti dara to!
Ibugbe Olorun, t’ oju ko ti ri;
Ta l’ o fe de ibe, lehin aiye yi?
Ta l’ o fe k’ a wo on ni aso funfun?
2 Awon wonni ni, t’ o ji nin’ orun won;
Awon t’ o ni ’gbagbo si nkan t’ a ko ri;
Awon t’ o k’ aniyan won l’ Olugbala,
Awon ti ko tiju agbelebu Krist.
3 Awon ti ko nani gbogbo nkan aiye
Awon t’ o le soto de oju iku,
Awon t’ o nrubo ife l’ ojojumo,
Awon t’ a f’ igbala Jesu ra pada.
4 Itiju ni fun nyin, Om’- ogun Jesu,
Enyin ara ilu ibugbe orun,
Kinla! e nfi fere at’ ilu sire,
’Gbat’ o ni k’e sise, t’o sip e, “E ja!”
5 B’ igbi omi aiye si ti nkolu wa,
Jesu Oba ogo, so si wa l’ eti,
Adun t’ o wa l’orun, ilu mino ni,
Nibi t’ isimi w alai ati lailai. Amin.