Hymn 246 E gbo iro orin ayo orun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 E gbo iro orin ayo orun,
Orin ayo ti isegun Jesu;
Gbogbo ota l’ o teri won ba fun,
Ese, iku, isa- oku pelu.
2 O se tan lati lo gba ijoba,
Fun Baba, Olorun ohun gbogbo;
O se tan lati lo gba iyin nla,
T’ o ye Olori- ogun ’gbala wa.
3 Ohun ikanu ni lilo Re, fun
Awon ayanfe omo- ehin Re.
E ma se konnu l’ oro itunu,
“Emi nlo pese aye nyin sile.”
4 Orun gba lo kuro lehin eyi,
Awosanma se Olugbala mo;
Awon Ogun- orun ho fun ayo,
Fun bibo Kristi Oluwa ogo.
5 E mase ba inu nyin je rara,
Jesu, ireti wa, yio tun wa;
Yio wa mu awon enia Re lo,
Sibiti nwon o bag be titilai. Amin.
