Hymn 243 Kristi, lehin isegun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Kristi, lehin isegun,
Iwo ti goke lo;
Kerub at’ ogun- orun
Wa sin O goke lo.
K’aiye so ’tan na jade
Emmanueli wa,
Ti s’ ara iy’ ara wa,
G’ ori ite Baba.
2 Nibe l’ o duro, t’ o nso
Agbara eje Re;
O mbebe fun elese,
’Wo Alagbawi wa.
Gbogbo ayidayida
T’ ayo, t’ aniyan wa,
N’ iwo nse iyonu si,
T’ iwo si mbebe fun.
3 Nitori itoye nla
Ti agbelebu Re,
K’ o fi Emi Re fun wa,
So ofo wa d’ ere.
Titi nipa iyanju,
Okan wa o goke;
Lati ba O gbe titi,
Li ayo ailopin. Amin.
