Hymn 24 Olorun wa Orun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Olorun wa Orun,
T’ o fi ojo mefa
Da nkan gbogbo ti mbe laiye
Simi n’ ijo keje.
2 O pase k’ a bowo
Fun ojo isimi;
Ibinu Re tobi pupo
S’ awon t’ o rufin yi.
3 Awon baba nla wa,
Ti ku nin’ okunkun;
Nwon je ogbo aborisa
Nwon ko mo ofin Re.
4 Awa de Oluwa,
Gege bi ase Re;
Lehin ise ijo mefa,
Lati se ife Re.
5 Mimo l’ ojo oni,
O ye ki a simi,
K’ a pejo ninu ile Re,
K’ a gbo ’ro mimo Re.
6 Isimi nla kan ku
F’ awon enia Re;
Om’ Olorun, Alabukun
Mu wa de ’simi Re ! Amin.